Ìṣẹ̀lẹ̀ Ajẹmọ́-Àwùjọ Òde-Òní nínú Ewì JF Ọdúnjọ

Main Article Content

sulaiman Fatai ibrahim

Abstract

Àṣamọ̀


Ohun tí iṣẹ́ yìí dá lé ni Ìṣẹ̀lẹ̀ Ajẹmọ́-Àwùjọ Òde-Òní nínú Ewì Joseph Fọláhàn Ọdúnjọ . Àwọn onímọ̀ tí wọ́n ti ṣe iṣẹ́ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ àwùjọ nínú ewì kò tíì ṣe àyẹ̀wò ìjẹyọ rẹ̀ nínú ewì Joseph Fọláhàn Ọdúnjọ. Nínú ewì Ọdúnjọ, a wò ó bí ó ṣé ń ewì rẹ̀ lé oríṣìíríṣìí ìṣẹ̀lẹ̀ àwùjọ. Ọgbọ́n ìwádìí tí a lò fún iṣẹ́ ìwádìí yìí ni ìlànà ìfọ̀rọ̀-wáni-lẹ́nu-wò tí a ṣe pẹ̀lú awọn onímọ̀ tí wọ́n ti ṣe iṣẹ́ lórí iṣẹ́-ọnà Ọdúnjọ rí. Yàtọ̀ sí èyí, a tún ka onírúurú ìwé  tí ó ti kọ bí i Aláwìíyé apá kìn-ín-ní títí kẹfà pàápàá jù lọ ìwé ewì rẹ̀ Àkójọpọ̀ Ewì Aládùn. Ìwádìí yìí fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé, bí àwọn akéwì-akọ̀wé bá túnbọ̀ gbájúmọ́ ìṣẹ̀lẹ̀ àwùjọ nínú iṣẹ́-ọnà pàápàá jù lọ nínú ewì, àwùjọ yóò ní ìdàgbàsókè tí ó péye ní gbogbo abala tí àwùjọ pín sí.


Kókó-Ọ̀rọ̀: Lítíréṣọ̀, Ewì, Joseph Fọláhàn Ọdúnjọ, Àwùjọ, Yorùbá.

Downloads

Download data is not yet available.

Article Details

Section

Articles