FÍÌMÙ YORÙBÁ : Ọ̀NÀ LÁTI TÁN ÌṢÒRO ORÍLẸ̀-ÈDÈ FÚN ÌDÀGBÀSÓKÈ

Main Article Content

IBRAHIM Wahab Adegbayi
SULAIMAN Fatai

Abstract

Ṣáájú kí àwọn òyìnbó tó dé sí Àwùjọ adúláwọ̀, pàápàá orílè-èdè Naijiria eré-oníṣẹ́ jẹ́ ọ̀nà kan pàtàkì tí àwùjọ ń gbà wá ojútùú sí àwọn ìṣòro tí àwùjọ tàbí ẹ̀dá àwùjọ ń kojú. Láàárín àwọn Yorùbá, eégún aláré àti àwọn ọdún ìbílẹ̀ ní tíátà tí wọ́n ń lò láti ṣe ìdánilẹ́kọ̀ọ́ àti ìdánilárayá láwùjọ wọn. Àwọn àgbékalẹ̀ méjèèjì yìí ni ọ̀nà pàtàkì tí àwọn àwùjọ máa ń fi mọ ohun tí ó ń lọ nílùú. Àwọn òṣèré eégún aláré máa ń ṣe àgbékalẹ̀ tí ó ní ṣe pẹ̀lú pípé àkíyèsí àwọn ènìyàn àwùjọ sì ọ̀rọ̀ tó ń lọ, kí àwọn tí ọ̀rọ̀ kan lè kó ara wọn ní ìjánu. Ojúṣe àwọn aláré yìí ni láti lè se ìtónisona fún àwọn onwòran, tí wọn jẹ ara ilu kí ilosiwaju lè bá eda kọ̀ọ̀kan  àti ìlú wọn, èyí tí yóò jẹ ìgbéga fún orílè-èdè. Pépà yìí ṣe àmúlò àwọn fíìmù Àgbéléwò Yorùbá bíi mélòó kan, láti wo ọ̀nà tí àwọn Oníṣẹ́ fíìmù tàbí àwọn àjọ òṣèré ń gbà wá ojútùú sì àwọn ìṣòro tí àwùjọ ń koju, kí ìdàgbàsókè lè bá irú àwùjọ bẹẹ. A gbìyànjú láti wo oríṣìíríṣìí fíìmù àti lé wo ọ̀nà tí wọ́n ń gbà pé àkíyèsí àwọn ènìyàn àwùjọ sì ọ̀nà tí orílẹ̀ èdè yìí Léfì bo nínú ìdààmú, ipayin keke tí a ń koju báyìí. Oríṣìíríṣìí fíìmù tí ó nise pẹ̀lú ona ati lè yanjú ìṣòro orílè èdè yìí là ń gbìyànjú láti wo, bákan náà ni a fi ọ̀rọ̀ wa àwọn onworan tàbí ara ilu lẹ́nu wo láti wo ipa fíìmù lórí wọn, lójú ọ̀nà àti wá ojútùú ìṣòro aìrìná, airilo, ọ̀wọ́n gógó oúnjẹ, igbenipa, ijinigbe, olè jíjà, yíyí ìbò, òògun olóró,àsìlò oogun àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Pépà yìí fihan pe fiimu lè tán ìṣòro tí orílè èdè yìí ń kojú, ti àwọn onworan bá ń fi ọkàn bá àwọn àgbékalẹ̀ yìí lọ, tí wọn sì ń ìṣàmúlò àwọn ìdánilẹ́kọ̀ọ́ inú àwọn fọ́nrán tí wọ́n wo fún ìdánilẹ́kọ̀ọ́ àti ìdánilárayá, láì kan máa wo fíìmù fún awẹ́wá tàbí ìgbádùn nìkan. Ó hàn gbangba pé, lítíréṣọ̀ tí àwọn ará ìlú feran lóòrè koore ni fíìmù jẹ́. Iṣẹ́ yìí fihàn pé tí àwọn ènìyàn bá lè kópa pàtàkì nínú àtúnṣe orílẹ̀ èdè, tí wọ́n bá ń sàmúlò ẹ̀kọ́ tí àwọn onífíìmù fẹ́ kí wọn kọ nínú awon àgbékalẹ̀ wọn.  Gbogbo ìwàgúnlẹ̀ fíìmù Yorùbá máa ń fi hàn pé, wọn fẹ́ kí àwọn ènìyàn máa kópa tí ó yanranti lórí ìdàgbàsókè àwùjọ wọn. This study examines how Yoruba films address societal issues, using them as a medium to educate and enlighten the community. The study also investigates how the audience perceives these films, whether as a means of entertainment or education. Furthermore, it explores the impact of these films on the audience and how they contribute to the development of the community and the country at large. The study reveals that films can be an effective tool for addressing societal issues. The study also shows that filmmakers often use their works to draw attention to pressing issues in the community and encourage positive change. The study recomends that filmmakers should endeavour to use their works to address societal issues and promote positive change The study concludes that if people can learn from the lessons portrayed in these films, it will lead to positive development in the community

Downloads

Download data is not yet available.

Article Details

Section

Articles

Author Biography

SULAIMAN Fatai , Department of Yorùbá Studies, Tai Solarin University of Education, Ijebu-ode, Nigeria.

Department of Yorùbá Studies, Tai Solarin University of Education, Ijebu-ode,
Nigeria.